Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ní ti àwọn ọmọ tí àwọn òbí wọ́n jẹ́ onígbàgbọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, Steven Carr Reuben, Ph.D., sọ nínú ìwé rẹ̀, Raising Jewish Children in a Contemporary World, pé: “Ó máa ń tojú sú àwọn ọmọ nígbà tí àwọn òbí wọ́n bá ń gbé ìgbésí ayé alábòsí, rúdurùdu, oníkọ̀kọ̀, tí wọ́n sì ń yẹra láti sọ̀rọ̀ nípa ìsìn. Nígbà tí àwọn òbí bá jẹ́ olóòótọ́, aláìlábòsí, tí wọ́n sì ṣe kedere nípa ìgbàgbọ́, ìlànà, àti àwòṣe ayẹyẹ wọn, àwọn ọmọ máa ń dàgbà pẹ̀lú ìfọ̀kànbalẹ̀ àti ìtóótun ara ẹni nínú àyíká ìsìn tí ó ṣe pàtàkì gidi fún ìdàgbàsókè iyì ara ẹni wọn látòkè délẹ̀ àti mímọ ipò wọn nínú ayé.”