Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Àwọn olùṣelámèyítọ́ kan gbìyànjú láti rọ ẹ̀sùn pé ó jẹ́ ayédèrú lójú nípa sísọ pé ńṣe ni ẹni tí ó kọ ọ́ fi orúkọ Dáníẹ́lì bojú, bí wọ́n ṣe lo àwọn awúrúju orúkọ fún àwọn ìwé ìgbàanì kan tí a kò kà sí ara Ìwé Mímọ́. Àmọ́, olùṣelámèyítọ́ Bíbélì náà, Ferdinand Hitzig, sọ pé: “Ọ̀ràn ti ìwé Dáníẹ́lì yàtọ̀ tí a bá fi lè sọ pé ẹlòmíràn ni [ó kọ ọ́]. A jẹ́ pé ayédèrú ìwé ni, ète rẹ̀ sì ni láti fi tan àwọn tí ó máa kà á nígbàanì jẹ, ṣùgbọ́n fún ire tiwọn ni ṣá.”