Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Kò sí Nábónídọ́sì nílé nígbà tí Bábílónì ṣubú. Nípa báyìí, lọ́nà ẹ̀tọ́, a júwe Bẹliṣásárì gẹ́gẹ́ bí ọba ní ìgbà náà. Àwọn olùṣelámèyítọ́ ń kùn pé àwọn àkọsílẹ̀ tí kì í ṣe ti ìsìn kò pe ọba mọ́ Bẹliṣásárì gẹ́gẹ́ bí orúkọ oyè rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ẹ̀rí tí ó jẹ́ ti ìgbàanì fi hàn pé àwọn ará ìgbà yẹn tilẹ̀ lè pe gómìnà pàápàá ní ọba.