Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Àsọtẹ́lẹ̀ inú Dáníẹ́lì orí Kọkànlá kò sàsọtẹ́lẹ̀ orúkọ àwọn alákòóso ìṣèlú tí yóò bọ́ sípò ọba àríwá àti ti ọba gúúsù ní ìgbà kọ̀ọ̀kan. Ẹ̀yìn ìgbà tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀ nìkan ni a tó máa ń dá wọn mọ̀. Ní àfikún sí i, níwọ̀n bí gídígbò wọn ti wáyé lọ́wọ̀ọ̀wọ́, àwọn ìgbà kan wà tí kò sí gídígbò rárá—tí ọba kan a máa ṣe bó ṣe wù ú, ìkejì a sì wà bí aláìsí.