Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Èrò tí àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan gbé jáde ni pé Mèsáyà, ẹni tó jẹ́ pé ó di ẹ̀yìn ìmúbọ̀sípò Jerúsálẹ́mù kó tó dé, ni gbólóhùn náà ‘èéhù Jèhófà’ tọ́ka sí. Bíbélì Aramaic Targums tún gbólóhùn yìí sọ lọ́rọ̀ mìíràn, ó kà báyìí pé: “Mèsáyà [Kristi] Jèhófà.” Ó wá ṣẹlẹ̀ pé ọ̀rọ̀ orúkọ yìí kan náà, (tseʹmach) lédè Hébérù, ni Jeremáyà tún lò lẹ́yìn náà nígbà tó pe Mèsáyà ní “èéhù kan tí ó jẹ́ olódodo” tí wọ́n gbé dìde fún Dáfídì.—Jeremáyà 23:5; 33:15.