Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
c Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ sọ pé ọ̀rọ̀ Hébérù tí a túmọ̀ sí “èmi kì yóò sì ṣojú àánú sí ènìyàn èyíkéyìí” jẹ́ “àpólà ọ̀rọ̀ tó ṣòroó” túmọ̀ “gan-an ni.” Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun fi ọ̀rọ̀ náà, “ṣojú àánú,” kún un láti fi lè jẹ́ kó hàn pé kò ní sí àyè fún ẹnikẹ́ni láti ti ibòmíràn wá láti wá gba Bábílónì sílẹ̀. Ìtumọ̀ Bíbélì kan, tí àwọn àjọ Jewish Publication Society ṣe, túmọ̀ àpólà ọ̀rọ̀ yìí báyìí: “Èmi . . . kì yóò gbà kí ẹnikẹ́ni bá a bẹ̀bẹ̀.”