Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Bí ìwé Targum ti Jonathan ben Uzziel (ti ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa), èyí tí J. F. Stenning túmọ̀ ṣe sọ ọ̀rọ̀ Aísáyà 52:13 ni pé: “Wò ó, ìránṣẹ́ mi, Ẹni Àmì Òróró (tàbí, Mèsáyà), yóò ṣàṣeyege.” Bákan náà, ìwé Babylonian Talmud, (ti nǹkan bí ọ̀rúndún kẹta Sànmánì Tiwa) sọ pé: “Mèsáyà tí à ń wí, kí lorúkọ rẹ̀ ná? . . . [; àwọn] ará ilé Rábì [pè é ní, Aláìsàn], nítorí wọ́n ti sọ ọ́ pé, ‘Dájúdájú, ó ti ru àìsàn wa.’”—Sànhẹ́dírìn 98b; Aísáyà 53:4.