Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
c Wọ́n tún máa ń lo ọ̀rọ̀ Hébérù tí a túmọ̀ sí “ìyọnu” fún ọ̀ràn àrùn ẹ̀tẹ̀. (2 Àwọn Ọba 15:5) Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àwọn ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ kan wí, Aísáyà 53:4 yìí ló mú kí àwọn Júù kan ní èrò pé adẹ́tẹ̀ ni Mèsáyà yóò jẹ́. Ìwé Babylonian Talmud sọ pé ọ̀rọ̀ Mèsáyà ni ẹsẹ yìí ń sọ, ló bá pe Mèsáyà ní “ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tó jẹ́ adẹ́tẹ̀.” Bíbélì Douay Version ti ìjọ Àgùdà túmọ̀ ẹsẹ kan náà yìí lọ́nà tí ẹ̀dà Vulgate lédè Látìn gbà túmọ̀ rẹ̀, ó ní: “A kà á sí ẹni tó dẹ́tẹ̀.”