Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Jèhófà ṣètò pé kí àwọn tó bá wọ gbèsè lára àwọn èèyàn rẹ̀ ta ara wọn sí oko ẹrú, ìyẹn ni pé kí wọ́n fi ara wọn háyà gẹ́gẹ́ bíi lébìrà, kí wọ́n fi lè san gbèsè wọn. (Léfítíkù 25:39-43) Àmọ́ Òfin náà sọ pé inúure ni kí wọ́n máa fi bá ẹrú lò. Èyí tí wọ́n bá ṣe ṣúkaṣùka nínú wọn ní láti dòmìnira.—Ẹ́kísódù 21:2, 3, 26, 27; Diutarónómì 15:12-15.