Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
c Nínú ìwé ti àwọn Másórẹ́tì tó jẹ́ èdè Hébérù, Aísáyà 65:16 sọ pé Jèhófà ni “Ọlọ́run tí í ṣe Àmín.” “Àmín” túmọ̀ sí “kí ó rí bẹ́ẹ̀” tàbí “ó ti dájú,” ó sì jẹ́ ọ̀rọ̀ tó ń fi hàn pé èèyàn fara mọ́ ohun tó gbọ́ tàbí pé ó dáni lójú pé ohun kan jẹ́ òótọ́ tàbí pé yóò ṣẹ dájúdájú. Bí Jèhófà sì ṣe mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ńṣe ló fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ òun.