Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Bí àpẹẹrẹ, àwọn apá kan wà nínú Bíbélì tó sọ nípa Jèhófà bíi pé ó ní ojú, etí, imú, ẹnu, apá àti ẹsẹ̀. (Sáàmù 18:15; 27:8; 44:3; Àìsáyà 60:13; Mátíù 4:4; 1 Pétérù 3:12) Àmọ́, èyí ò túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ní ojú, etí, imú, ẹnu, apá àti ẹsẹ̀ bíi tàwa èèyàn. Ó ṣe tán, a ò ní ronú pé Jèhófà jẹ́ òkè gìrìwò torí pé Bíbélì pè é ní “Àpáta náà” bẹ́ẹ̀ la ò sì ní ronú láé pé ó dà bí irin tọ́mọ ogun kan fi ń dáàbò bo ara ẹ̀ torí pé Bíbélì pè é ní “apata.”—Diutarónómì 32:4; Sáàmù 84:11.