Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ ìṣe náà phi·leʹo láti ṣàpèjúwe ìfẹ́ tó wà láàárín ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tàbí ọmọ ìyá, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n lo ọ̀rọ̀ yìí nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Ọ̀rọ̀ náà stor·geʹ túmọ̀ sí ìfẹ́ tẹ́nì kan ní sáwọn tí wọ́n jọ wà nínú ìdílé. Ọ̀rọ̀ yìí ni wọ́n lò ní 2 Tímótì 3:3, ẹsẹ náà sì sọ pé irú ìfẹ́ yìí máa ṣọ̀wọ́n láwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Ọ̀rọ̀ náà Eʹros túmọ̀ sí ìfẹ́ tó wà láàárín ọkùnrin àti obìnrin. Wọn ò lo ọ̀rọ̀ yìí nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, àmọ́ Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa irú ìfẹ́ yẹn.—Òwe 5:15-20.