Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ọ̀pọ̀ ìgbà tí Bíbélì bá sọ̀rọ̀ nípa ìrètí àjíǹde ló máa ń rán wa létí agbára tí Jèhófà ní láti rántí nǹkan. Ọkùnrin olóòótọ́ náà Jóòbù, sọ fún Jèhófà pé: “Ká ní . . . o yan àkókò kan sílẹ̀ fún mi, kí o sì rántí mi!” (Jóòbù 14:13) Jésù náà sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde “gbogbo àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí.” Òótọ́ sì lọ̀rọ̀ yìí, torí pé gbogbo àwọn òkú tí Jèhófà ní lọ́kàn láti jí dìde ló rántí dáadáa.—Jòhánù 5:28, 29.