Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́ kan yọ ọ̀rọ̀ yìí kúrò nínú Lúùkù 23:34. Àmọ́, ó wà nínú ọ̀pọ̀ ìwé àfọwọ́kọ míì tó ṣeé gbára lé, torí náà a ò yọ ọ́ nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ó sì tún wà nínú ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì míì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ọmọ ogun Róòmù tó kan Jésù mọ́gi ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ ọ̀rọ̀ yìí. Ká sòótọ́, wọn ò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe, torí wọn ò mọ ẹni tí Jésù jẹ́ gan-an. Ó tún ṣeé ṣe káwọn Júù tó ní kí wọ́n pa Jésù wà lára àwọn tí Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ ọ̀rọ̀ yẹn, torí àwọn kan lára wọn ronú pìwà dà nígbà tó yá. (Ìṣe 2:36-38) Àmọ́, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn jẹ̀bi ní tiwọn, torí bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù, wọ́n fúngun mọ́ àwọn ará Róòmù pé kí wọ́n pa á. Torí náà, Ọlọ́run ò lè dárí ji ọ̀pọ̀ lára wọn.—Jòhánù 11:45-53.