Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Kùránì sọ̀rọ̀ nípa ìbí Jésù lọ́nà iṣẹ́ ìyanu nínú Surah 19 (Mariyama), Al-Kuránì Ti A Tumọ si Ède Yoruba. Ó sọ pé: “Awa si ran ẹmi wa si (Mariyama), o si fi ara hãn gẹgẹbi ọkunrin ti o mọ kan. On (Mariyama) wipe: Emi sadi Ọba Ajọkẹ aiye kuro lọdọ rẹ bi irẹ ba jẹ olubẹru (Ọlọhun). On (Malaika) wipe: Dajudaju iranṣẹ Oluwa rẹ ni emi jẹ pe: Emi yio fun ọ ni (iro) ọmọkunrin ti o mọ kan. (Mariyama) wipe: Bawo ni ọdọmọkunrin yio ṣe wa fun mi nigbati abara kan kò fọwọkan mi bẹni emi kò si jẹ àgbèrè (panṣaga). O wipe: Bẹni yio jẹ. Oluwa rẹ wipe: Ọ rọrun fun Mi (lati ṣe); atipe ki A le ṣe e ni arisami fun awọn enia ati anu lati ọdọ Wa. O si jẹ ọ̀rọ ti a ti pari.”