Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Kò sí ọ̀rọ̀ náà, “ẹ̀rí ọkàn,” nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Àmọ́, àpẹẹrẹ Jóòbù tá a mẹ́nu kàn níhìn-ín fi hàn pé àwọn èèyàn ní ẹ̀rí ọkàn. Ọ̀rọ̀ náà “ọkàn-àyà” sábà máa ń túmọ̀ sí ẹni tá a jẹ́ ní inú. Èyí fi hàn pé Jóòbù tẹ́tí sí apá pàtàkì kan lára ẹni tó jẹ́ ní inú, ìyẹn ẹ̀rí ọkàn rẹ̀. Iye ìgbà tá a lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ẹ̀rí ọkàn” nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tó ọgbọ̀n.