Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Lẹ́ẹ̀kan lọ́gbọ̀n, Kristẹni kan lè ṣẹ Kristẹni bíi tiẹ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀ bíburú jáì nípa fífipá bá a lò pọ̀, gbígbéjà kò ó, pípa á, tàbí jíjà á lólè. Nínú irú àwọn ọ̀ràn bí èyí, kò lòdì sí ẹ̀kọ́ Kristẹni pé kéèyàn jẹ́ káwọn aláṣẹ gbọ́ nípa rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé irú ẹ̀ lè yọrí sí ìgbẹ́jọ́ nílé ẹjọ́ tàbí bíbá onítọ̀hún ṣẹjọ́ ọ̀daràn.