Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé àwa èèyàn ní ìmọ̀lára kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀, tó máa ń jẹ́ kára wa mọ bó ṣe yẹ kóun wà, àti ibi tó yẹ ká gbé apá àti ẹsẹ̀ wa sí. Bí àpẹẹrẹ, ìmọ̀lára yìí ló máa ń jẹ́ ká lè pàtẹ́wọ́ bá a tiẹ̀ dijú. A tiẹ̀ rí aláìsàn kan tó jẹ́ àgbàlagbà tí kò lè dìde dúró, tí kò lè rìn, àní tí kò lè dìde jókòó pàápàá nígbà tí irú ìmọ̀lára yìí daṣẹ́ sílẹ̀ lára ẹ̀.