a Ẹni yìí kì í ṣe àpọ́sítélì Fílípì o. Àmọ́ bá a ṣe sọ ní Orí 5, òun ni Fílípì tó wà lára àwọn ‘ọkùnrin méje tí wọ́n lórúkọ rere’ tí wọ́n yàn láti máa bójú tó pípín oúnjẹ láàárín àwọn Kristẹni opó tó ń sọ èdè Gíríìkì àtàwọn tó ń sọ èdè Hébérù ní Jerúsálẹ́mù.—Ìṣe 6:1-6.