Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Ṣáájú àsìkò yẹn, ó dájú pé ìgbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun bá ṣèrìbọmi ni Ọlọ́run máa ń fi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n. Èyí ló mú kí wọ́n nírètí láti jẹ́ ọba àti àlùfáà pẹ̀lú Jésù ní ọ̀run. (2 Kọ́r. 1:21, 22; Ìfi. 5:9, 10; 20:6) Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, Ọlọ́run ò fẹ̀mí mímọ́ yan àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun náà nígbà tí wọ́n ṣèrìbọmi. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìgbà tí Pétérù àti Jòhánù gbọ́wọ́ lé wọn ni wọ́n tó gba ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́, tí wọ́n sì láǹfààní láti máa ṣe iṣẹ́ ìyanu.