Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé, òfin Késárì kan fi dandan lé e nígbà yẹn pé ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ èyíkéyìí nípa “ọba tàbí ìjọba tuntun kan pé ó ń bọ̀, pàápàá tó bá jẹ́ pé irú ọba bẹ́ẹ̀ máa ṣẹ́gun tàbí ṣèdájọ́ olú ọba tó ń ṣàkóso lọ́wọ́.” Ó ṣeé ṣe káwọn alátakò yìí ti ṣi ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù lóye, kí wọ́n sì gbà pé ó ti rú òfin yìí. Wo àpótí náà, “Àwọn Olú Ọba Tó Ṣàkóso Lákòókò Tí Wọ́n Kọ Ìwé Ìṣe.”