Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Tẹ́túlọ́sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Fẹ́líìsì torí pé “àlàáfíà púpọ̀” wà lórílẹ̀-èdè wọn nígbà tó jẹ́ gómìnà. Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé kó tó di pé àwọn èèyàn ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba Róòmù, rògbòdìyàn tó wà ní Jùdíà nígbà tí Fẹ́líìsì fi jẹ́ gómìnà pọ̀ ju èyí tó wà nígbà táwọn gómìnà tó jẹ ṣáájú rẹ̀ fi wà lórí oyè. Ohun míì tó tún jẹ́ ẹ̀tàn nínú ohun tí Tẹ́túlọ́sì sọ ni pé nígbà táwọn Júù rí àwọn àtúnṣe tí Fẹ́líìsì ti ṣe, ‘wọ́n dúpẹ́ wọ́n tọ́pẹ́ dá.’ Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ló kórìíra Fẹ́líìsì torí pé ó ń ni wọ́n lára, tó sì hùwà ìkà sí wọn nígbà tó dí wọn lọ́wọ́ láti ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba.—Ìṣe 24:2, 3.