Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Dáníẹ́lì 1:1, 2 sọ pé Jèhófà fi Jèhóákímù lé Nebukadinésárì lọ́wọ́ ní ọdún kẹta ìjọba Jèhóákímù, bóyá ìyẹn sì jẹ́ lọ́dún kẹta tó ti ń ṣàkóso lábẹ́ Bábílónì. Èyí lè fi hàn pé ìgbà ìsàgatì tí wọ́n fi ṣẹ́gun ìlú yẹn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ni ọba yìí kú. Àmọ́ ṣá o, kò sí ẹ̀rí kankan nínú Bíbélì tó ti ìtàn tí ọ̀gbẹ́ni Josephus kọ pé Nebukadinésárì pa Jèhóákímù, ó sì ní kí wọ́n ju òkú rẹ̀ sẹ́yìn odi Jerúsálẹ́mù láì sin ín.—Jer. 22:18, 19; 36:30.