Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Àwọn kan gbà pé ìtòsí ni Jeremáyà lọ dípò iyànníyàn Odò Yúfírétì. Kí nìdí tí wọ́n fi sọ bẹ́ẹ̀? Ọ̀mọ̀wé kan tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì sọ pé: “Ìdí kan ṣoṣo táwọn aṣelámèyítọ́ yìí fi sọ bẹ́ẹ̀ ni pé, wọ́n wò ó pé wàhálà ìrìn àjò ẹ̀ẹ̀méjì tàlọ tàbọ̀ láti Jerúsálẹ́mù lọ sí iyànníyàn Odò Yúfírétì á ti pọ̀ jù fún wòlíì náà.”