Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
c Òṣùwọ̀n mẹ́fà ọkà bálì ni Bóásì bù fún Rúùtù, àmọ́ Bíbélì kò sọ ohun tó fi díwọ̀n rẹ̀. Bóyá ńṣe ni Bóásì ṣe bẹ́ẹ̀ láti fi hàn pé bí ìsinmi Sábáàtì ṣe máa ń tẹ̀ lé ọjọ́ iṣẹ́ mẹ́fà, bákan náà ni Ọlọ́run ṣe máa tó fi ọkọ àti ilé aláyọ̀ rọ́pò gbogbo ọjọ́ tí Rúùtù ti fi jìyà gẹ́gẹ́ bí opó. Ó sì lè jẹ́ pé ohun tó fà á tó fi bu òṣùwọ̀n mẹ́fà, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ẹ̀kún ṣọ́bìrì mẹ́fà, fún Rúùtù ni pé kò lè gbé ju ìyẹn lọ.