Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Lára ohun tí ẹ̀jẹ́ àwọn Násírì ò fàyè gbà ni pé kí wọ́n mu ọtí líle tàbí kí wọ́n gé irun orí wọn. Àkókò díẹ̀ ni èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn fi máa ń wà lábẹ́ ẹ̀jẹ́ yìí, àmọ́ àwọn díẹ̀ bíi Sámúsìnì, Sámúẹ́lì àti Jòhánù Oníbatisí jẹ́ Násírì jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn.