Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Àgọ́ ìjọsìn yìí jẹ́ ilé onígun mẹ́rin tí wọ́n fi àwọn ọwọ̀n onígi gbé ró. Àmọ́, àwọn ohun èlò tó níye lórí jù lọ láyé ìgbà yẹn ni wọ́n fi kọ́ ọ, irú bí awọ séálì, àwọn aṣọ tí wọ́n ṣiṣẹ́ ọ̀nà aláràbarà sí àti àwọn igi olówó gọbọi tí wọ́n fi wúrà àti fàdákà bò. Àárín àgbàlá onígun mẹ́rin ni àgọ́ ìjọsìn náà wà, pẹpẹ ńlá kan tí wọ́n fi ń rúbọ sì wà níbẹ̀. Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, wọ́n kọ́ àwọn yàrá míì tí àwọn àlùfáà á máa lò sí ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ àgọ́ ìjọsìn náà. Ó jọ pé ọ̀kan lára àwọn yàrá yẹn ni Sámúẹ́lì ń sùn.