Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
c Ìtàn yìí sọ méjì lára irú ìwà àìlọ́wọ̀ bẹ́ẹ̀. Àkọ́kọ́ ni pé, Òfin sọ àwọn ohun tó yẹ kí wọ́n fún àwọn àlùfáà láti jẹ lára ọrẹ ẹbọ. (Diu. 18:3) Ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà burúkú tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó yàtọ̀. Ńṣe ni wọ́n máa ń sọ fún àwọn ìránṣẹ́ wọn pé kí wọ́n ki àmúga bọ ẹran tó ń hó lọ́wọ́ nínú ìkòkò, kí wọ́n sì mú èyí tó dára jù lọ nínú àwọn ẹran tó bá gbé jáde! Èkejì ni pé, nígbà táwọn èèyàn bá mú ẹbọ tí wọ́n fẹ́ sun wá síbi pẹpẹ, àwọn àlùfáà burúkú náà á ní kí ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ fi tipátipá gba ẹran tútù lọ́wọ́ ẹni tó wá rúbọ, kó tiẹ̀ tó di pé wọ́n fi ọ̀rá ẹran náà rúbọ sí Jèhófà.—Léf. 3:3-5; 1 Sám. 2:13-17.