Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Ó ṣeé ṣe kí Dáfídì máa rò ó pé iṣẹ́ ìsìn sí Jèhófà Ọlọ́run ni òun ń ṣe bí òun ṣe ń dáàbò bo àwọn onílẹ̀ àgbègbè yẹn àti agbo ẹran wọn. Nígbà yẹn, ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé kí àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù máa gbé ilẹ̀ náà. Torí náà, dídáàbò bo ilẹ̀ yẹn lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá àtàwọn agbésùnmọ̀mí jẹ́ iṣẹ́ ìsìn sí Ọlọ́run.