Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Kíyè sí i pé ohun tí Bíbélì sọ nípa ìrìn àjò yìí yàtọ̀ sí ohun tó sọ nípa èyí tí Màríà lọ tẹ́lẹ̀. Ní ti ìyẹn, Bíbélì sọ pé: “Màríà dìde . . . ó sì lọ” ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Èlísábẹ́tì. (Lúùkù 1:39) Màríà àti Jósẹ́fù ti ń fẹ́ra wọn sọ́nà nígbà yẹn, àmọ́ wọn ò tíì ṣègbéyàwó, torí náà Màríà lè má sọ fún Jósẹ́fù kó tó lọ. Lẹ́yìn ìgbéyàwó wọn, Jósẹ́fù ló sọ pé ìrìn àjò yá, kì í ṣe Màríà.