Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
c Bó ṣe jẹ́ pé ìta làwọn olùṣọ́ àgùntàn ti ń tọ́jú àgbo ẹran wọn ní àkókò yìí jẹ́ ká rí i pé òótọ́ ni Bíbélì sọ nípa ìgbà tí wọ́n bí Jésù. Oṣù December kọ́ ni wọ́n bí Kristi torí tòsí ilé ni àwọn olùṣọ́ àgùntàn ti máa ń tọ́jú agbo ẹran wọn lásìkò yẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, nǹkan bí ìbẹ̀rẹ̀ oṣù October ni wọ́n bí i.