Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Láwùjọ àwọn Júù ti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, wọn kì í sábà jẹ́ kí àwọn obìnrin kópa nínú ohun tó bá jẹ mọ́ ẹ̀kọ́ ìwé. Iṣẹ́ ilé ni wọ́n sábà máa ń kọ́ wọn jù. Torí náà, Màtá lè máa wò ó pé kò bọ́ sí i rárá kí obìnrin wá jókòó kalẹ̀ síbi tí olùkọ́ kan ti ń kọ́ni kó máa kẹ́kọ̀ọ́.