Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Lámékì sọ orúkọ ọmọ rẹ̀ ní Nóà, tó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Ìsinmi” tàbí “Ìtùnú.” Ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé orúkọ yìí máa ro Nóà lóòótọ́ nítorí ó máa kó àwọn èèyàn yọ nínú làálàá tí wọ́n ń ṣe lórí ilẹ̀ tí Ọlọ́run fi gégùn-ún. (Jẹ́n. 5:28, 29) Ṣùgbọ́n Lámékì kú kí àsọtẹ́lẹ̀ yìí tó ṣẹ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìyá Nóà, àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò rẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin bá ìkún-omi lọ.