Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
c Ohun tí kò jẹ́ kí àwọn ìkìlọ̀ ìgbà yẹn lágbára tó bó ṣe yẹ ni pé àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tó jẹ́ agbo kékeré nìkan ni wọ́n ń sọ pé àwọn ìkìlọ̀ yẹn kàn ní pàtàkì. A máa rí i ní Orí 5 ìwé yìí pé ṣáájú ọdún 1935, wọ́n rò pé ọ̀kẹ́ àìmọye ọmọ ìjọ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ni yóò wà nínú àwọn tí Bíbélì Mímọ́ pè ní “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn” nínú Ìṣípayá 7:9, 10 àti pé wọ́n á di ẹgbẹ́ onípò kejì tó ń lọ sí ọ̀run gẹ́gẹ́ bí èrè pé ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín ni wọ́n tó fara mọ́ Kristi.