Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àkókò yẹn lè gùn gan-an lójú àwa èèyàn òde òní, ká má gbàgbé pé nígbà yẹn, ẹ̀mí àwọn èèyàn máa ń gùn gan-an ju ti ìsinsìnyí. Èèyàn mẹ́rin péré látorí Ádámù sí Ábúráhámù, bá ara wọn láyé. Ìyẹn ni pé Lámékì baba Nóà bá Ádámù láyé, Ṣémù ọmọ Nóà bá Lámékì láyé, Ábúráhámù sì bá Ṣémù láyé.—Jẹ́n. 5:5, 31; 9:29; 11:10, 11; 25:7.