Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
c Ìgbà méjìdínlógún ni orúkọ náà “Sátánì” fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù. Àmọ́ ó ju ìgbà ọgbọ̀n lọ tí orúkọ náà “Sátánì” fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ lédè Gíríìkì. Bó ṣe yẹ kó rí náà nìyẹn, torí Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù kò fi bẹ́ẹ̀ pàfiyèsí sí ọ̀rọ̀ nípa Sátánì, bí a ṣe máa dá Mèsáyà mọ̀ ló gbájú mọ́. Ìgbà tí Mèsáyà dé ló wá táṣìírí Sátánì ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, tí wọ́n sì wá kọ ọ́ sínú ìwé Mímọ́ lédè Gíríìkì.