Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Lọ́dún 1932, Apá Kejì ìwé Vindication jẹ́ ká kọ́kọ́ mọ̀ pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó dá lórí bí àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe máa pa dà sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn tún ní ìmúṣẹ lóde òní, àmọ́ kì í ṣe ara àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ló ṣẹ sí bí kó ṣe Ísírẹ́lì tẹ̀mí. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ń tọ́ka sí ìmúbọ̀sípò ìjọsìn mímọ́. Ilé Ìṣọ́ March 1, 1999, ṣàlàyé pé ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí jẹ́ ará àsọtẹ́lẹ̀ tó fi hàn pé ìjọsìn mímọ́ máa pa dà bọ́ sípò, torí náà ìran náà máa kó ipa pàtàkì nínú ìjọsìn ní ọjọ́ ìkẹyìn.