Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Báwo la ṣe mọ̀ pé Baba kọ́ Ọmọ rẹ̀ bó ṣe máa kọ́ni? Rò ó wò ná: Ọ̀pọ̀ àwọn àpèjúwe tí Jésù lò nígbà tó ń kọ́ àwọn èèyàn jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ kan tá a ti kọ sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún kí wọ́n tó bí i. (Sm. 78:2; Mát. 13:34, 35) Ó ṣe kedere pé tipẹ́tipẹ́ ni Jèhófà tó jẹ́ Orísun àsọtẹ́lẹ̀ náà ti pinnu pé Ọmọ òun máa lo àwọn àpèjúwe tàbí àkàwé láti fi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́.—2 Tím. 3:16, 17.