Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ní ọdún 2013, àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tí wọ́n fọwọ́ sí pé kí wọ́n máa bá ìgbìmọ̀ ìkọ́lé ẹlẹ́kùnjẹkùn méjìléláàdóje [132] tó wà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣiṣẹ́ ju ẹgbàá márùndínlọ́gọ́fà [230,000] lọ. Ní orílẹ̀-èdè yẹn, ọdọọdún ni àwọn ìgbìmọ̀ yẹn máa ń ṣe kòkáárí kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun tó tó márùndínlọ́gọ́rin [75] tí wọ́n sì ń ṣèrànwọ́ láti ṣe àtúnṣe àwọn gbọ̀ngàn tó tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún [900].