Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ó jọ pé ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé ìparun àwọn ètò ẹ̀sìn nìkan ni ìparun “Bábílónì Ńlá” jẹ́ ní pàtàkì, kì í ṣe pé wọ́n máa pa gbogbo àwọn èèyàn tó ń ṣe ẹ̀sìn wọ̀nyẹn. Torí náà, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó wà nínú àwọn ẹ̀sìn Bábílónì Ńlá tẹ́lẹ̀ ni yóò la ìparun yẹn, ó sì jọ pé, ó kéré tán wọ́n á fi hàn ní gbangba pé àwọn kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ìsìn, bí a ṣe rí i ní Sekaráyà 13:4-6.