Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Jèhófà ń tipa bẹ́ẹ̀ sọ fáwọn èèyàn náà pé òun ò ní jẹ́ kí wọ́n sọ ilé mímọ́ òun dìdàkudà bíi ti tẹ́lẹ̀, ó sọ pé: “Wọ́n fi ohun ìríra tí wọ́n ń ṣe sọ orúkọ mímọ́ mi di ẹlẹ́gbin bí wọ́n ṣe gbé ibi àbáwọlé wọn sí ẹ̀gbẹ́ ibi àbáwọlé mi, tí wọ́n sì gbé férémù ẹnu ọ̀nà wọn sí ẹ̀gbẹ́ férémù ẹnu ọ̀nà mi, ògiri nìkan ló sì wà láàárín èmi àti àwọn.” (Ìsík. 43:8) Nílùú Jerúsálẹ́mù àtijọ́, ṣe làwọn èèyàn kọ́lé gbe tẹ́ńpìlì náà, ọpẹ́lọpẹ́ ògiri tó yí i ká. Torí náà, bí wọ́n ṣe pa ìlànà òdodo Jèhófà tì, ṣe ni wọ́n mú ìwà ẹ̀gbin àti ìbọ̀rìṣà wọn sún mọ́ tòsí ilé Jèhófà. Kò sí àní-àní pé ohun ìríra gbáà nìyẹn!