Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
c Jésù sọ ohun tó fara jọ èyí nínú àpèjúwe nípa àwọ̀n ńlá. Àwọ̀n náà kó ẹja tó pọ̀ gan-an, àmọ́ kì í ṣe gbogbo ẹja ọ̀hún ló “dáa.” Ṣe ni wọ́n máa da àwọn ẹja tí kò dáa nù. Jésù tipa báyìí kìlọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí àwọn kan lára àwọn tó ń wá sínú ètò Jèhófà ya aláìṣòótọ́ nígbà tó bá yá.—Mát. 13:47-50; 2 Tím. 2:20, 21.