Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Adehun yii ni akọkọ ati eyi ti o ṣe pataki julọ ninu awọn ọ̀wọ́ iwe adehun tí Canada, United States, Soviet Union, ati awọn orilẹ-ede 32 miiran, fọwọsi ni Helsinki. Orukọ adehun pataki naa ti a faṣẹ si ni Ofin Ìkẹhìn ti Àpérò lori Ailewu ati Ifọwọsowọpọ ni Europe. Gongo rẹ̀ akọkọ ni lati dín àìfararọ jakejado awọn orilẹ-ede laaarin Ila-oorun ati Iwọ-oorun kù.—World Book Encyclopedia.