Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Awọn oluṣewadii lẹnu aipẹ yii ti rí ibatan kan ti ó wà laaarin ìwà-ipá pọ́ńbélé lori tẹlifiṣọn ati ìwà-ọ̀daràn awọn màjèṣí. Awọn adugbo nibi ti ìwà-ọ̀daràn ti gbode ati awọn ilé ti ó túká tun jẹ́ kókó abajọ pẹlu ninu ìwà àìbẹ́gbẹ́pé. Ni Germany ti Nazi ìgbékèéyíde elérò igbagbọ ẹ̀yà-ìran-tèmi-lọ̀gá aláìdabọ̀ sún awọn kan lati dáre fun—ati ki wọn tilẹ fogo fun—awọn ìwà ìkà-òǹrorò lodisi awọn Ju ati awọn ti ń sọ èdè Slavic.