Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Àwọn elérò ọ̀rọ̀-ẹ̀dá-kò-kan-Ọlọ́run jẹ́wọ́ pé, bí i ti ẹnì kan tí ń ṣe agogo, Ọlọrun fi ìṣẹ̀dá rẹ̀ sẹ́nu iṣẹ́ ó sì wá dẹ̀yìn kọ gbogbo rẹ̀ pátá, ní dídá àgunlá àguntẹ̀tẹ̀ sí i. Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà The Modern Heritage ti sọ, àwọn elérò ọ̀rọ̀-ẹ̀dá-kò-kan-Ọlọrun “gbàgbọ́ pé àìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun jẹ́ ìṣìnà kan tí ó ti ọwọ́ àwọn ènìyàn tí kò ní ìrètí wá ṣùgbọ́n pé ìgbékalẹ̀ ọlọ́lá-àṣẹ ti Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki àti àìṣe é yípadà àti ojú-ìwòye tèmi lọ̀gá ti àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ rẹ̀ tilẹ̀ tún múni banújẹ́ jù.”