Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Nígbà tí Bibeli sọ pé “ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni oun yoo ká pẹlu,” èyí kò túmọ̀sí pé ìjìyà ẹnì kan gbọ́dọ̀ jẹ́ ìyà-ibi láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. (Galatia 6:7, NW) Nínú ayé ti Satani jọba lé lórí yìí, àwọn olódodo sábà máa ń dojúkọ ìṣòro púpọ̀ ju àwọn ènìyàn burúkú lọ. (1 Johannu 5:19) Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin yoo sì jẹ́ ohun ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn nítìtorí orúkọ mi.” (Matteu 10:22, NW) Àìsàn àti irú àwọn àgbákò mìíràn lè ṣe ẹnikẹ́ni nínú àwọn olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Ọlọrun.—Orin Dafidi 41:3; 73:3-5; Filippi 2:25-27.