Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ó lé ní 70 ibi nínú àkọsílẹ̀ Ìròyìnrere níbi tí a ti kọ ọ́ sílẹ̀ pé Jesu lo gbólóhùn tí ó ṣàrà ọ̀tọ̀ láti tẹnumọ́ ìjótìítọ́ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó máa ń sábà sọ pé “Àmín” (“Ní òótọ́,” NW) láti bẹ̀rẹ̀ gbólóhùn kan. Ọ̀rọ̀ Heberu tí ó bá a mu túmọ̀ sí “ohun tí ó dájú, ohun tí ó jẹ́ òtítọ́.” Ìwé atúmọ̀ èdè The New International Dictionary of New Testament Theology sọ pé: “Nípa bíbẹ̀rẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àmín Jesu fi wọ́n hàn pé wọ́n dájú wọ́n sì ṣeé gbáralé. Ó dúró ti ọ̀rọ̀ rẹ̀ ó sì mú kí wọ́n ní agbára lórí òun fúnra rẹ̀ àti àwọn olùgbọ́ rẹ̀. Wọ́n jẹ́ àwọn gbólóhùn ọlá-ńlá àti ọlá àṣẹ rẹ̀.”