Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Àpótí aláwọ jẹ́ àpótí kékeré aláwọ onígun mẹ́rin tí ó ní àwọn ìwé pelebe tí ó ní àwọn ìpínrọ̀ Ìwé Mímọ́ nínú. Àwọn àpótí yìí ni a máa ń so mọ́ ọwọ́ òsì àti mọ orí nígbà àdúrà òwúrọ̀ ti àárín ọ̀sẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́. Àkájọ ẹsẹ̀ Bibeli jẹ́ àkájọ awọ kékeré tí a kọ Deuteronomi 6:4-9 àti 11:13-21 sí, tí a fi sínú àpótí tí a kàn mọ́ àtẹ́rígbà.