Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ìgò aláwọ ni ìkóǹkansí tí a fi awọ ẹranko ṣe láti gba nǹkan bí omi, òróró, wàrà, wáìnì, bọ́tà, àti wàràkàṣì dúró. Ìtóbi àti ìrísí àwọn ìgò ìgbàanì máa ń yàtọ̀ síra lọ́pọ̀lọpọ̀, àwọn kan nínú wọn máa ń jẹ́ àpamọ́wọ́ tí a fi awọ ṣe, àwọn mìíràn sì máa ń ní ọrùn tín-ínrín tí ó ní ìdérí.