Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Àmọ́ ṣáá o, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ tí ó ní ìtumọ̀ gbígbòòrò, ọ̀rọ̀ náà, neʹphesh, tún ní àwọn ìtumọ̀ míràn tí ó yàtọ̀. Fún àpẹẹrẹ, ó lè tọ́ka sí ẹni ti inú lọ́hùn-ún, ní pàtàkì nígbà tí a bá ń tọ́ka sí ìmọ̀lára jíjinlẹ̀. (Sámúẹ́lì Kìíní 18:1) Ó tún lè tọ́ka sí ìwàláàyè tí ẹnì kan ń gbádùn gẹ́gẹ́ bí ọkàn kan.—Àwọn Ọba Kìíní 17:21-23.